Jeremiah 42:20 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
pé ẹ ti fi ẹ̀mí ara yín wéwu nítorí ìṣìnà yín. Nítorí pé nígbà tí ẹ rán mi sí OLUWA Ọlọrun yín pé kí n gbadura fun yín, gbogbo ohun tí OLUWA Ọlọrun yín bá wí ni kí n sọ fun yín, ẹ ní ẹ óo sì ṣe é.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori ọkàn nyin li ẹnyin tanjẹ, nigbati ẹnyin rán mi si Oluwa, Ọlọrun nyin, wipe, Gbadura fun wa si Oluwa, Ọlọrun wa: ati gẹgẹ bi gbogbo eyi ti Oluwa Ọlọrun wa yio wi, bẹ̃ni ki o sọ fun wa, awa o si ṣe e.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Pé àṣìṣe ńlá gbáà ni ẹ̀yin ṣe nígbà tí ẹ̀yin rán mi sí OLÚWA Ọlọ́run yín pé, ‘Gbàdúrà sí OLÚWA Ọlọ́run wa fún wa; sọ fún wa gbogbo ohun tí ó bá sọ, àwa yóò sì ṣe é.’