Jeremiah 42:5 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọ́n wí fún Jeremaya pé, “Kí OLUWA ṣe ẹlẹ́rìí òtítọ́ ati òdodo bí a kò bá ṣe gbogbo nǹkan tí OLUWA Ọlọrun bá ní kí o sọ fún wa.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si wi fun Jeremiah pe, ki Oluwa ki o ṣe ẹlẹri otitọ ati ododo lãrin wa, bi awa kò ba ṣe gẹgẹ bi gbogbo ọ̀rọ ti Oluwa, Ọlọrun rẹ, yio rán ọ si wa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni wọ́n sọ fún Jeremáyà wí pé, “Kí OLÚWA ṣe ẹlẹ́rìí òtítọ́ àti òdodo láàrin wa, bí àwa kò bá ṣe gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí OLÚWA Ọlọ́run rẹ bá rán ọ láti sọ fún wa.