Jeremiah 43:10 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
kí o sì wí fún wọn pé OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní òun óo lọ mú Nebukadinesari ọba Babiloni, iranṣẹ òun wá, yóo sì gbé ìtẹ́ rẹ̀ ka orí àwọn òkúta tí òun rì mọ́lẹ̀ yìí, Nebukadinesari yóo sì tẹ́ ìtẹ́ ọlá rẹ̀ sórí wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki o si wi fun wọn pe, Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli, wi, pe, wò o, emi o ranṣẹ, emi o si mu Nebukadnessari, ọba Babeli, iranṣẹ mi, emi o si gbe itẹ rẹ̀ kalẹ lori okuta wọnyi, ti emi ti fi pamọ; on o si tẹ itẹ ọla rẹ̀ lori wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Báyìí kí o sì sọ fún wọn pé, ‘Èyí ni ohun tí Ọlọ́run alágbára, Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí: Èmi yóò ránsẹ́ sí ìránṣẹ́ mi Nebukadinésárì Ọba Bábílónì Èmi yóò gbé ìjọba rẹ̀ ka orí àwọn òkúta; èyí tí mo ti rì sí ibí yìí, yóò tan ìjọba rẹ̀ jù wọ́n lọ.