Jeremiah 43:2 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Asaraya, ọmọ Hoṣaaya, ati Johanani, ọmọ Karea, ati gbogbo àwọn ọkunrin aláfojúdi kan wí fún Jeremaya pé, “Irọ́ ni ò ń pa. OLUWA Ọlọrun wa kò rán ọ láti sọ fún wa pé kí á má lọ ṣe àtìpó ní Ijipti.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni Asariah, ọmọ Hoṣaiah, ati Johanani, ọmọ Karea, ati gbogbo awọn agberaga enia, wi fun Jeremiah pe, Iwọ ṣe eke! Oluwa, Ọlọrun wa, kò ran ọ lati wipe, Ẹ má lọ si Egipti lati ṣatipo nibẹ:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ásáríyà ọmọ Hòsáyà àti Jóhánánì ọmọ Káréà, àti gbogbo àwọn agbéraga ọkùnrin sọ fún Jeremáyà pé, “Irọ́ ló ń pa! OLÚWA Ọlọ́run wa kò rán ọ láti sọ pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ lọ sí Éjíbítì láti tẹ̀dó síbẹ̀.’