Jeremiah 43:5 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Kàkà bẹ́ẹ̀, Johanani, ọmọ Karea, ati gbogbo àwọn olórí ogun kó gbogbo àwọn ará Juda tí wọ́n ṣẹ́kù, tí wọ́n pada wá sí ilẹ̀ Juda láti oríṣìíríṣìí orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti sálọ:
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Johanani, ọmọ Karea, ati gbogbo awọn olori ogun, si mu gbogbo iyokù Juda, ti nwọn pada lati gbogbo orilẹ-ède wá, ni ibi ti a ti le wọn si, lati ma gbe ilẹ Juda;
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Dípò bẹ́ẹ̀, Jóhánánì ọmọ Káréà àti àwọn ọ̀gágun sì ko àwọn àjẹkù Júdà tí wọ́n wá láti gbé ilẹ̀ Júdà láti orílẹ̀-èdè gbogbo tí wọ́n ti tú wọn ká.