Jeremiah 43:6 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
àwọn ọkunrin ati àwọn obinrin, àwọn ọmọde, àwọn ìjòyè, ati gbogbo àwọn tí Nebusaradani, olórí àwọn ẹ̀ṣọ́ ọba Babiloni, fi sábẹ́ àkóso Gedalaya ọmọ Ahikamu, ọmọ Ṣafani, ati Jeremaya wolii ati Baruku ọmọ Neraya.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn ọkunrin, ati awọn obinrin, ati awọn ọmọde, ati awọn ọmọbinrin ọba, ati gbogbo enia ti Nebusaradani, balogun iṣọ, ti kù silẹ lọdọ Gedaliah, ọmọ Ahikamu, ọmọ Ṣafani, ati Jeremiah woli, ati Baruku, ọmọ Neriah,
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n tún kó àwọn ọkùnrin, àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé, àti àwọn ọmọ Ọba tí ó jẹ́ obìnrin èyí tí Nebusàrádánì tí ó jẹ́ adarí ogun ọ̀wọ́ tí ó jẹ́ olùsọ́ ti fi sílẹ̀ pẹ̀lú Jedaháyà ọmọ Élíkámù, ọmọ Sáfánì, àti Jeremáyà wòlíì náà àti Bárúkù ọmọ Néríà.