Jeremiah 44:12 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
N óo run gbogbo àwọn tí wọ́n ṣẹ́kù ní ilẹ̀ Juda tí wọ́n gbójú lé àtilọ máa gbé ilẹ̀ Ijipti, wọn kò ní ku ẹyọ kan ní ilẹ̀ Ijipti. Gbogbo wọn ni wọn óo parun láti orí àwọn mẹ̀kúnnù dé orí àwọn eniyan pataki pataki; ogun ati ìyàn ni yóo pa wọ́n. Wọn yóo di ẹni ìfibú, ẹni àríbẹ̀rù, ẹni ègún ati ẹni ẹ̀sín.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi o si mu gbogbo iyokù Juda, ti o ti gbe oju wọn si ati lọ si ilẹ Egipti, lati ṣatipo nibẹ, gbogbo wọn ni yio si run, nwọn o si ṣubu ni ilẹ Egipti; nwọn o si run nipa idà ati nipa ìyan, nwọn o kú lati ẹni-kekere wọn titi de ẹni-nla wọn, nipa idà, ati nipa ìyan: nwọn o si di ẹni-ègun, ẹni-iyanu, ati ẹni-ẹ̀gan, ati ẹsin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi yóò sì mú àwọn èérún tí ó kù ní Júdà, tí wọ́n ṣetán láti lọ Éjíbítì. Wọn yóò ṣubú pẹ̀lú idà tàbí kí wọn kú pẹ̀lú ìyàn láti orí ọmọdé títí dé àgbà ni wọn yóò kú láti ọwọ́ ìyàn tàbí idà. Wọn yóò di ẹni ìfiré àti ìparun, ẹni ẹ̀kọ̀ àti ẹni ẹ̀gàn.