Jeremiah 44:14 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹnikẹ́ni kò ní yè ninu àwọn tí wọ́n ṣẹ́kù ní Juda, tí wọ́n lọ fi ilẹ̀ Ijipti ṣe ilé; wọn kò ní sá àsálà, wọn kò sì ní yè, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní pada sí ilẹ̀ Juda tí ọkàn wọn fẹ́ pada sí. Wọn kò ní pada, àfi àwọn bíi mélòó kan ni wọ́n óo sá àsálà.’ ”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Kì o si si ẹniti o sala, ati ẹniti o kù, fun awọn iyokù Juda, ti o wọ ilẹ Egipti lati ma ṣatipo nibẹ, ti yio pada si ilẹ Juda, si eyiti nwọn ni ifẹ ati pada lọ igbe ibẹ: nitori kò si ọkan ti yio pada bikoṣe iru awọn ti o sala.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kò sí èyí tí ó kéré jù nínú Júdà tí ó kù, tí ó ń gbé ilẹ̀ Éjíbítì tí yóò sá àsálà padà sórí ilẹ̀ Júdà, èyí tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ láti padà sí, àti láti máa gbé; àyàfi àwọn aṣàtìpó mèlòó kan.”