Jeremiah 44:15 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Lẹ́yìn náà, gbogbo àwọn ọkunrin tí wọ́n mọ̀ pé àwọn iyawo wọn ń sun turari sí àwọn oriṣa ati àwọn obinrin tí wọ́n pọ̀ gbáà tí wọn wà nítòsí ibẹ̀, ati àwọn tí wọn ń gbé Patirosi ní ilẹ̀ Ijipti, wọ́n bá dá Jeremaya lóhùn,
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni gbogbo awọn ọkunrin ti nwọn mọ̀ daju pe, awọn aya wọn ti sun turari fun ọlọrun miran, ati gbogbo awọn obinrin ti o duro nibẹ, apejọ nla, ati gbogbo awọn enia ti ngbe ilẹ Egipti ani ni Patrosi, da Jeremiah lohùn, wipe,
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Lẹ́yìn èyí, gbogbo àwọn ọkùnrin tí ẹ bá mọ̀ pé, ìyàwó wọn sun tùràrí sí àwọn òrìṣà pẹ̀lú àwọn obìnrin tí ó bá wá àwọn ènìyàn púpọ̀, pàápàá àwọn ènìyàn tí wọ́n ń gbé ní òkè àti ìsàlẹ̀ Éjíbítì, bẹ́ẹ̀ ni a wí fún Jeremáyà.