Jeremiah 44:17 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn a óo máa san gbogbo ẹ̀jẹ́ wa, a óo máa sun turari sí ọbabinrin ojú ọ̀run, oriṣa wa, a óo sì máa ta ohun mímu sílẹ̀, bí àwa ati àwọn baba ńlá wa, ati àwọn ọba wa ati àwọn olórí wa ti ṣe ní gbogbo ìlú Juda ati ní ìgboro Jerusalẹmu; nítorí pé nígbà náà à ń jẹ oúnjẹ ní àjẹyó, ó dára fún wa, ojú wa kò sì rí ibi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn dajudaju awa o ṣe ohunkohun ti o jade lati ẹnu wa wá, lati sun turari fun ayaba ọrun, ati lati da ẹbọ ohun mimu fun u, gẹgẹ bi awa ti ṣe, awa, ati awọn baba wa, awọn ọba wa, ati awọn ijoye wa ni ilu Juda, ati ni ita Jerusalemu: nigbana awa ni onjẹ pupọ, a si ṣe rere, a kò si ri ibi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Dájúdájú; à ó ṣe gbogbo nǹkan tí a sọ pé à ò ṣe: A ó sun tùràrí sí ayaba ọ̀run; à ó sì da ohun mímu sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹbọ sí àwa àti àwọn baba wa, àwọn Ọba àti àwọn aláṣẹ ti ṣe ní àwọn ìlú Júdà àti ni àwọn ìgboro Jérúsálẹ́mù. Nígbà naà àwa ní ounjẹ púpọ̀ a sì ṣe rere a kò sì rí ibi