Jeremiah 44:19 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn obinrin bá tún dáhùn pé, “Nígbà tí à ń sun turari sí ọbabinrin ojú ọ̀run, tí a sì ń rú ẹbọ ohun mímu sí i, ṣé àwọn ọkọ wa ni kò mọ̀ pé à ń ṣe àkàrà dídùn, tí à ń ṣe bí ère rẹ̀ fún un ni, ati pé à ń ta ohun mímu sílẹ̀ fún un?”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati nigbati awa sun turari fun ayaba ọrun ti a si da ẹbọ ohun mimu fun u, lẹhin awọn ọkọ wa ni awa ha dín akara didùn rẹ̀ lati bọ ọ, ti a si da ẹbọ ohun mimu fun u bi?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Obìnrin náà fi kun-un pé, “Nígbà tí à ń jó tùràrí sí ayaba ọ̀run, tí a sì ń fi ohun mímu rúbọ si; ǹjẹ́ àwọn ọkọ wa kò mọ pé àwa ń ṣe àkàrà bí i, àwòrán rẹ, àti wí pé à ń da ọtí si gẹ́gẹ́ bi ohun ìrúbọ?”