Jeremiah 44:21 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Ṣebí OLUWA ranti turari tí ẹ̀yin ati àwọn baba yín, ati àwọn ọba yín, ati àwọn ìjòyè yín, ati gbogbo àwọn eniyan ilẹ̀ náà sun ninu àwọn ìlú Juda ati ní ìgboro Jerusalẹmu, ṣebí OLUWA ranti.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Turari ti ẹnyin sun ni ilu Juda ati ni ita Jerusalemu, ẹnyin ati awọn baba nyin, awọn ọba nyin, ati awọn ijoye nyin, ati awọn enia ilẹ na, Oluwa kò ha ranti rẹ̀, kò ha si wá si ọkàn rẹ̀?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ṣe Ọlọ́run kò rántí ẹbọ sísun ní ìlú Júdà àti àwọn ìgboro Jérúsálẹ́mù láti ọ̀dọ̀ rẹ àti ọ̀dọ̀ àwọn bàbá rẹ, àwọn Ọba àti àwọn aláṣẹ àti àwọn ènìyàn ìlú.