Jeremiah 44:25 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní, ‘Ẹ̀yin ati àwọn iyawo yín ti fi ẹnu ara yín sọ, ẹ sì ti fi ọwọ́ ara yín mú ohun tí ẹ wí ṣẹ pé, “Dájúdájú a ti jẹ́jẹ̀ẹ́ sí oriṣa ọbabinrin ojú ọ̀run láti sun turari sí i, ati láti rú ẹbọ ohun mímu sí i.” ’ Kò burú, ẹ mú ẹ̀jẹ́ yín ṣẹ!
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli sọ, wipe, Ẹnyin ati awọn aya nyin, ẹnyin fi ẹnu nyin sọ̀rọ, ẹ si fi ọwọ nyin mu ṣẹ, ẹ si wipe, lõtọ awa o san ẹ̀jẹ́ wa ti awa ti jẹ, lati sun turari fun ayaba ọrun, ati lati da ẹbọ ohun mimu fun u, njẹ ni pipamọ, ẹ pa ẹ̀jẹ́ nyin mọ, ati ni sisan ẹ san ẹ̀jẹ́ nyin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èyí ni ọ̀rọ̀ tí OLÚWA àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí: Ìwọ àti àwọn Ìyàwó rẹ fihàn pẹ̀lú àwọn ìhùwà rẹ àti àwọn ohun tí ó ṣèlérí nígbà tí o wí pé, ‘Àwa yóò mú ẹ̀jẹ́ tí a jẹ́ lórí sísun tùràrí àti dída ọtí sí orí ère ayaba ọ̀run ṣẹ.’ “Tẹ̀ṣíwájú nígbà náà, ṣe ohun tí o sọ, kí o sì mú ẹ̀jẹ́ rẹ ṣẹ.