Jeremiah 44:26 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí náà, ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA wí, gbogbo ẹ̀yin ará Juda tí ẹ̀ ń gbé ilẹ̀ Ijipti: Ó ní, ‘Ẹ wò ó, mo ti fi orúkọ ńlá mi búra pé àwọn ará Juda tí wọ́n wà ní Ijipti kò ní fi orúkọ mi búra mọ́ pé “Bí OLUWA ti wà láàyè.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina ẹ gbọ́ ọ̀rọ Oluwa, gbogbo Juda ti ngbe ilẹ Egipti, sa wò o, emi ti fi orukọ nlanla mi bura, li Oluwa wi, pé, a kì yio pè orukọ mi li ẹnu ọkunrin-kunrin Juda ni gbogbo ilẹ Egipti, wipe, Oluwa, Ọlọrun wà.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n gbọ ọ̀rọ̀ OLÚWA, gbogbo ẹ̀yin Júù tí ń gbé ilẹ̀ Éjíbítì, mo gégùn-ún: ‘Mo búra pẹ̀lú títóbi orúkọ mi,’ bẹ́ẹ̀ ni OLÚWA, ‘wí pé, kò sí ẹnikẹ́ni láti Júdà tí ń gbé ibikíbi ní Éjíbítì ni tí ó gbọdọ̀ ké pe orúkọ mi tàbí búra. “Gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run tí ó dá wa ti wà láàyè.”