Jeremiah 44:27 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Mo dójúlé yín láti ṣe yín ní ibi. Ibi ni n óo ṣe yín, n kò ní ṣe yín ní oore. Gbogbo àwọn ará Juda tí wọ́n wà ní Ijipti ni ogun ati ìyàn yóo pa láìku ẹnìkan.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Wò o, emi o ṣọ wọn fun ibi, kì si iṣe fun rere: ati gbogbo awọn ọkunrin Juda ti o wà ni ilẹ Egipti ni a o run nipa idà, ati nipa ìyan, titi nwọn o fi tan.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí náà, mò ń wò wọ́n bí i fún ìparun, kì í ṣe fún rere. Àwọn Júù tí ó wà ní Éjíbítì yóò parun pẹ̀lú idà àti ìyàn títí tí gbogbo wọn yóò fi parun.