Jeremiah 44:28 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn eniyan díẹ̀ ni wọn yóo sá àsálà kúrò ní ilẹ̀ Ijipti lọ sí ilẹ̀ Juda. Gbogbo àwọn tí wọ́n bá ṣẹ́kù ní Juda, tí wọ́n lọ sí Ijipti yóo wá mọ ọ̀rọ̀ ẹni tí yóo ṣẹ, bóyá tèmi ni, tabi tiwọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati awọn ti o sala lọwọ idà, yio pada ni iye diẹ lati ilẹ Egipti si ilẹ Juda; ati gbogbo iyokù Juda, ti o lọ si ilẹ Egipti lati ṣatipo nibẹ, yio mọ̀ ọ̀rọ tani yio duro, temi, tabi ti wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn tí ó bá sá àsálà kúrò lọ́wọ́ ìparun idà àti pípadà sí ilẹ̀ Júdà láti Éjíbítì yóò kéré níye. Gbogbo àwọn tí ó bá kú ní ilẹ̀ Júdà, tí ó wá gbé ilẹ̀ Éjíbítì yóò mọ ọ̀rọ̀ ẹni tí yóò dúró yálà tèmi tàbí ti yín.