Jeremiah 44:30 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Èmi OLUWA ni mo sọ ọ́ pé n óo fi Farao Hofira ọba Ijipti lé ọ̀tá rẹ̀ lọ́wọ́ ati àwọn tí wọn ń wá ẹ̀mí rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí mo ti fi Sedekaya, ọba Juda lé ọwọ́ ọ̀tá rẹ̀, Nebukadinesari, ọba Babiloni, ẹni tí ó ń wá ọ̀nà láti pa á.’ ”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bayi li Oluwa wi; wò o, emi o fi Farao-hofra, ọba Egipti, le ọwọ awọn ọta rẹ̀, ati le ọwọ awọn ti nwá ẹmi rẹ̀; gẹgẹ bi emi ti fi Sedekiah, ọba Juda, le ọwọ Nebukadnessari, ọba Babeli ọta rẹ̀, ti o si wá ẹmi rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Báyìí ni OLÚWA wí: ‘Èmi yóò fi Fáráò Hópírà Ọba Éjíbítì lé àwọn ọ̀tá rẹ̀ lọ́wọ́, èyí tí ó lè pa ayé rẹ́; gẹ́gẹ́ bí mo ti fi Sedekáyà Ọba Júdà lé Nebukadinésárì Ọba Bábílónì lọ́wọ́ ọ̀tá tó ń lépa ẹ̀mí rẹ̀.’ ”