Jeremiah 44:6 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Mo bá bínú gan-an sí àwọn ìlú Juda ati ìgboro Jerusalẹmu; mo sì sọ wọ́n di aṣálẹ̀ ati ahoro bí wọ́n ti wà lónìí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina ni mo ṣe dà ìrunu mi ati ibinu mi jade, a si daná rẹ̀ ni ilu Juda, ati ni ita Jerusalemu: nwọn si di ofo ati ahoro, gẹgẹ bi ti oni yi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Fún ìdí èyí, ìbínú gbígbóná mi ni èmi yóò yọ sí àwọn ìlú Júdà àti òpópó Jérúsálẹ́mù àti sísọ wọ́n di ìparun bí ó ṣe wà lónìí yìí.