Jeremiah 44:7 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Èmi, OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli wá ń bi yín léèrè pé, ‘Kí ló dé tí ẹ fi ń ṣe ara yín ní ibi tó báyìí? Ṣé ẹ fẹ́ kó gbogbo àwọn eniyan wọnyi kúrò ní ilẹ̀ Juda, ati àwọn ọkunrin ati àwọn obinrin, àtọmọ ọmú, àtọmọ ọwọ́, títí tí kò fi ní ku ẹnikẹ́ni ninu yín lẹ́yìn ni?
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Njẹ nisisiyi, bayi li Oluwa, Ọlọrun awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli, wi pe, nitori kini ẹ ṣe da ẹ̀ṣẹ nla yi si ọkàn nyin, lati ke ninu nyin ani ọkunrin ati obinrin, ati ọmọde ati ọmọ-ọmu, kuro lãrin Juda, lati má kù iyokú fun nyin;
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Báyìí tún ni OLÚWA Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun Ísírẹ́lì wí: Kí ló dé tí ẹ fi ń mu ibi ńlá yìí wá sí orí ara yín nípa yíyapa kúrò lára Júdà ọkùnrin àti obìnrin, ọmọdé àti èwe, tí ẹ kò sì ku ọ̀kankan?