Jeremiah 44:8 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Kí ló dé tí ẹ fi ń fi iṣẹ́ ọwọ́ yín bí mi ninu, tí ẹ̀ ń sun turari sí àwọn oriṣa ní ilẹ̀ Ijipti, níbi tí ẹ̀ ń gbé? Ṣé ẹ fẹ́ kí n pa yín run, kí ẹ di ẹni ẹ̀sín láàrin gbogbo orílẹ̀-èdè ayé ni ẹ ṣe ń ṣe báyìí?
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ninu eyiti ẹnyin fi iṣẹ ọwọ nyin mu mi binu, ni sisun turari fun ọlọrun miran ni ilẹ Egipti, nibiti ẹnyin lọ lati ṣatipo, ki ẹ le ke ara nyin kuro, ati ki ẹ le jẹ ẹni-ègun ati ẹsin, lãrin gbogbo orilẹ-ède ilẹ aiye?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èéṣe tí ẹ fi mú mi bínú pẹ̀lu ohun tí ọwọ́ yín ṣe pẹ̀lú ẹbọ sísun sí àwọn òrìṣà Éjíbítì, níbi tí ẹ wá láti máa gbé? Ẹ̀ ò pa ara yín run, ẹ̀ ó sì sọ ara yín di ẹni ìfiré àti ẹ̀gàn láàrin àwọn orílẹ̀ èdè ayé gbogbo.