Jeremiah 44:9 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣé ẹ ti gbàgbé ibi tí àwọn baba ńlá yín ṣe ní ilẹ̀ Juda ati ìgboro Jerusalẹmu, tí àwọn ọba Juda ati àwọn ayaba ṣe ati ẹ̀yin pẹlu àwọn iyawo yín?
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹnyin ha ti gbagbe ìwa-buburu awọn baba nyin, ati ìwa-buburu awọn ọba Juda, ati ìwa-buburu awọn aya wọn, ati ìwa-buburu ẹnyin tikara nyin, ati ìwa-buburu awọn aya nyin, ti nwọn ti hù ni ilẹ Juda, ati ni ita Jerusalemu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣé ẹ̀yin ti gbàgbé ibi tí àwọn bàbá ńlá yín àti àwọn Ọba; àwọn ayaba Júdà, àti àwọn ibi tí ẹ ti ṣe àti àwọn ìyàwó yín ní ilẹ̀ Júdà àti ní òpópó Jérúsálẹ́mù?