Jeremiah 45:5 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ìwọ ń wá nǹkan ńlá fún ara tìrẹ? Má wá nǹkan ńlá fún ara rẹ. Wò ó, n óo mú kí ibi bá gbogbo eniyan, èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀; ṣugbọn n óo jẹ́ kí o máa sá àsálà ní gbogbo ibi tí o bá ń lọ.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Iwọ ha si mbere ohun nla fun ara rẹ? máṣe bere: nitori, wò o, emi o mu ibi wá sori gbogbo ẹran-ara, li Oluwa wi: ṣugbọn ẹmi rẹ li emi o fi fun ọ bi ikogun ni gbogbo ibiti iwọ ba lọ si.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣé ìwọ yóò wá ohun rere fún ara rẹ? Nítorí náà, má ṣe wá wọn. Èmi yóò mú ibi wá sí orí àwọn ènìyàn gbogbo ni OLÚWA wí. Níbikíbi tí o bá lọ ni èmi yóò jẹ́ kí o sá àsálà ẹ̀mí rẹ ní àlàáfíà.’ ”