Jeremiah 46:10 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ọjọ́ OLUWA àwọn ọmọ ogun ni ọjọ́ náà, ọjọ́ ẹ̀san, tí yóo gbẹ̀san ara rẹ̀ lára àwọn ọ̀tá rẹ̀. Idà rẹ̀ yóo pa àpatẹ́rùn, yóo sì mu ẹ̀jẹ̀ wọn ní àmuyó. Nítorí OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun ní ń rúbọ, ní ìhà àríwá, lẹ́bàá odò Yufurate.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn ọjọ yi li ọjọ igbẹsan Oluwa, Ọlọrun awọn ọmọ-ogun, ki o le gbẹsan lara awọn ọta rẹ̀; idà yio si jẹ, yio si tẹ́ ẹ lọrun, a o si fi ẹ̀jẹ wọn mu u yo: nitori Oluwa, Ọlọrun awọn ọmọ-ogun, ni irubọ ni ilẹ ariwa lẹba odò Euferate.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n ọjọ́ náà jẹ́ ti OLÚWA Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, ọjọ́ ìgbẹ̀san, ìgbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá rẹ̀. Idà yóò sì jẹ́ títí yóò fi ní ìtẹ́lọ́rùn, títí yóò fi pa òrùngbẹ rẹ̀ rẹ́ pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀. Nítorí pé OLÚWA Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun yóò rúbọ ní ilẹ̀ Gúṣù ní odò Ẹ́fúrétà.