Jeremiah 46:16 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ogunlọ́gọ̀ yín ti fẹsẹ̀ kọ, wọ́n sì ṣubú, wọ́n wá ń wí fún ara wọn pé, ‘Ẹ dìde, ẹ jẹ́ kí á pada sọ́dọ̀ àwọn eniyan wa, ati sí ilẹ̀ tí wọn gbé bí wa, nítorí ogun àwọn aninilára.’
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
A sọ awọn ti o kọsẹ di pupọ, lõtọ, ẹnikini ṣubu le ori ẹnikeji: nwọn si wipe, Dide, ẹ jẹ ki a pada lọ sọdọ awọn enia wa, ati si ilẹ ti a bi wa, kuro lọwọ idá aninilara.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọn yóò máa ṣubú léraléra wọn yóò máa ṣubú lu ara wọn. Wọn yóò sọ wí pé, ‘Ẹ dìde, ẹ jẹ́ kí a padà sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn wa àti ilẹ̀ ìbí wa, kúrò níbi idà àwọn aninilára.’