Jeremiah 46:2 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ọ̀rọ̀ lórí Ijipti: Nípa àwọn ọmọ ogun Farao Neko, ọba Ijipti, tí wọ́n wà létí odò Yufurate ní Kakemiṣi, àwọn tí Nebukadinesari, ọba Babiloni, ṣẹgun ní ọdún kẹrin tí Jehoiakimu ọmọ Josaya jọba Juda.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Si Egipti, si ogun Farao-Neko, ọba Egipti, ti o wà lẹba odò Ferate ni iha Karkemiṣi, ti Nebukadnessari, ọba Babeli, kọlu ni ọdun kẹrin Jehoiakimu, ọmọ Josiah, ọba Juda.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nípa Éjíbítì, Èyí ni ọ̀rọ̀ nípa àwọn ọmọ ogun Fáráò Nékò Ọba Éjíbítì ẹni tí a borí rẹ̀ ní Káṣímísì, ní odò Ẹ́fúrétà láti ọwọ́ Nebukadinésárì Ọba Bábílónì ní ọdún kẹrin Jéhóáíkímù ọmọ Jòsáyà Ọba Júdà: