Jeremiah 46:21 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn ọmọ ogun tí ó fi owó bẹ̀ lọ́wẹ̀, dàbí akọ mààlúù àbọ́pa láàrin rẹ̀; àwọn náà pẹ̀yìndà, wọ́n ti jọ sálọ, wọn kò lè dúró; nítorí ọjọ́ ìdààmú wọn ti dé bá wọn, ọjọ́ ìjìyà wọn ti pé.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn ologun rẹ̀ ti a fi owo bẹ̀, dabi akọmalu abọpa lãrin rẹ̀; awọn wọnyi pẹlu yi ẹhin pada; nwọn jumọ sa lọ pọ: nwọn kò duro, nitoripe ọjọ wàhala wọn de sori wọn, àkoko ibẹwo wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn jagunjagun rẹ̀ dàbí àbọ́pa màlúù. Àwọn pẹ̀lú yóò yípadà, wọn ó sì jùmọ̀ sá, wọn kò ní le dúró, Nítorí tí ọjọ́ ibi ńbọ̀ lórí wọn àsìkò láti jẹ wọ́n níyà.