Jeremiah 46:23 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọn yóo gé igi inú igbó rẹ̀ lulẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé igbó náà dí, nítorí pé igi ibẹ̀ pọ̀ bí eṣú, tí wọn kò sì lóǹkà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn o ke igbo rẹ̀ lulẹ, li Oluwa wi, nitori ti a kò le ridi rẹ̀; nitoripe nwọn pọ̀ jù ẹlẹnga lọ, nwọn si jẹ ainiye.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọn o gé igbó rẹ̀ lulẹ̀,” ni OLÚWA wí, “nítorí ti a kò le rídìí rẹ̀, nítorí pé wọ́n pọ̀ ju elẹ́ǹgà lọ, wọ́n sì jẹ́ àìníye.