Jeremiah 46:25 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní: “N óo fi ìyà jẹ Amoni, oriṣa Tebesi, ati Farao, ati Ijipti pẹlu àwọn oriṣa rẹ̀, ati àwọn ọba rẹ̀. N óo fìyà jẹ Farao ati àwọn tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé e.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli, wipe; Wò o, emi o bẹ̀ Amoni ti No, ati Farao, ati Egipti wò, pẹlu awọn ọlọla wọn, ati awọn ọba wọn; ani Farao ati gbogbo awọn ti o gbẹkẹ le e:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
OLÚWA àwọn ọmọ-ogun jùlọ, Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí pé: “Èmi ṣetán láti fi ìyà jẹ Ámónì, òrìṣà Tíbísì, Fáráò Éjíbítì àti àwọn òrìṣà rẹ̀ àti àwọn Ọba rẹ̀ àti àwọn tó gbẹ́kẹ̀lé Fáráò.