Jeremiah 46:27 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Ṣugbọn ẹ má bẹ̀rù, ẹ̀yin ọmọ Jakọbu, iranṣẹ mi, ọmọ Israẹli, ẹ má fòyà; n óo gbà yín là láti ọ̀nà jíjìn, n óo kó arọmọdọmọ yín yọ ní ilẹ̀ ìgbèkùn. Ẹ̀yin ọmọ Jakọbu, ẹ óo pada máa gbé ní ìrọ̀rùn. Kò sì ní sí ẹni tí yóo dẹ́rù bà yín.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn iwọ má bẹ̀ru, iwọ Jakobu, ọmọ-ọdọ mi, má si fòya, iwọ Israeli: nitori, wo o, emi o gbà ọ là lati okere wá, ati iru-ọmọ rẹ lati ilẹ ìgbekun wọn; Jakobu yio si pada, yio si wà ni isimi, yio si gbe jẹ, ẹnikan kì o si dẹ̀ru bà a.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Má bẹ̀rù, ìwọ Jákọ́bù ìránṣẹ́ mi, má fòyà, ìwọ Ísírẹ́lì. Dájúdájú èmi ó gbà ọ́ láti ọ̀nà jínjìn, àwọn ọmọ ọmọ rẹ ní ilẹ̀ ìgbèkùn. Jákọ́bù yóò tún ní àlàáfíà àti ààbò, kò sì sí ẹni tí yóò dẹ́rù bà á.