Jeremiah 46:28 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹ má bẹ̀rù, ẹ̀yin ọmọ Jakọbu, iranṣẹ mi, nítorí pé mo wà pẹlu yín. N óo run gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí mo le yín lọ, ṣugbọn n kò ní pa yín run. Bí ó bá tọ́ kí n jẹ yín níyà, n óo jẹ yín níyà, kìí ṣe pé n óo fi yín sílẹ̀ láìjẹ yín níyà. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Iwọ má bẹ̀ru, iwọ Jakobu, ọmọ-ọdọ mi, li Oluwa wi: nitori emi wà pẹlu rẹ; nitori emi o ṣe opin patapata ni gbogbo awọn orilẹ-ède, nibiti emi ti le ọ si: ṣugbọn emi kì o ṣe ọ li opin patapata, ṣugbọn emi o ba ọ wi ni ìwọn; sibẹ emi kì yio jọ̃ rẹ lọwọ li alaijiya.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Má bẹ̀rù, Jákọ́bù ìránṣẹ́ mi, nítorí pé mo wà pẹ̀lú rẹ,” bẹ́ẹ̀ ni OLÚWA wí. “Bí mo tilẹ̀ pa gbogbo orílẹ̀ èdè run, láàrin àwọn tí mo fọ́n yín ká sí. Èmi kò ní run yín tán. Èmi yóò jẹ ọ́ níyà lórí òdodo, èmi kò ní fi ọ́ sílẹ̀ láìjẹ ọ́ níyà.”