Jeremiah 46:5 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Oluwa ní, “Kí ni mo rí yìí? Ẹ̀rù ń bà wọ́n, wọ́n sì ń pada sẹ́yìn. A ti lu àwọn ọmọ ogun wọn bolẹ̀, wọ́n sì ń sálọ pẹlu ìkánjú; wọn kò bojú wẹ̀yìn, ìpayà yí wọn ká!
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẽṣe ti emi ti ri wọn ni ibẹ̀ru ati ni ipẹhinda? awọn alagbara wọn li a lù bolẹ, nwọn sa, nwọn kò si wò ẹhin: ẹ̀ru yika kiri, li Oluwa wi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kí ni nǹkan tí mo tún rí? Wọ́n bẹ̀rù, wọ́n sì ń padà sẹ́yìn, wọ́n ti ṣẹ́gun àwọn jagunjagun. Wọ́n sá, wọn kò sì bojú wẹ̀yìn, ìbẹ̀rù sì wà níbi gbogbo,” ni OLÚWA wí.