Jeremiah 46:8 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ijipti ń ru bí odò Naili, bí odò tí ó kún bo bèbè rẹ̀. Ijipti wí pé, ‘N óo kún, n óo sì bo ayé mọ́lẹ̀, n óo pa àwọn ìlú ati àwọn tí wọn ń gbé inú wọn run.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Egipti dide bi odò Nile, omi rẹ̀ si nrú bi omi odò wọnni; o si wipe, Emi o goke lọ, emi o si bò ilẹ aiye, emi o si pa ilu ati awọn olugbe inu rẹ̀ run!
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Éjíbítì dìde bí odò náà, bí omi odò tí ń ru. Ó sì wí pé, ‘Èmi yóò dìde, n ó sì bo gbogbo ilẹ̀ ayé.’ Èmi yóò pa orílẹ̀ èdè àti àwọn ènìyàn rẹ̀ run.