Jeremiah 47:2 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ó ní, “Wò ó, omi kan ń ru bọ̀ láti ìhà àríwá, yóo di àgbàrá tí ó lágbára; yóo ya bo ilẹ̀ yìí ati gbogbo ohun tí ó wà lórí rẹ̀, yóo ya bo ìlú yìí pẹlu, ati àwọn tí wọn ń gbé inú rẹ̀. Àwọn eniyan yóo kígbe: gbogbo àwọn ará ìlú yóo sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bayi li Oluwa wi; Wò o, omi dide lati ariwa, yio si jẹ kikun omi akunya, yio si ya bo ilẹ na, ati gbogbo ẹkún inu rẹ̀; ilu na, ati awọn ti ngbe inu rẹ̀: nigbana ni awọn enia yio kigbe, gbogbo awọn olugbe ilẹ na yio si hu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Báyìí ni OLÚWA wí: “Wo bí omi ti ń ru sókè ní àríwá, wọn ó di odò tí ń bo bèbè mọ́lẹ̀. Wọn ò ní borí ilẹ̀ àti ohun gbogbo tó wà lórí rẹ̀, ìlú àti àwọn tó ń gbé nínú wọn. Àwọn ènìyàn yóò kígbe; gbogbo ẹni tó ń gbé lórí ilẹ̀ yóò pohùnréré ẹkún