Jeremiah 47:3 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí pátákò ẹsẹ̀ ẹṣin bá ń dún, tí àwọn kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ bá ń sáré, tí ẹsẹ̀ àwọn kẹ̀kẹ́ ogun sì ń pariwo, Àwọn baba kò ní lè wo àwọn ọmọ wọn lẹ́yìn pé kí àwọn fà wọ́n, nítorí pé ọwọ́ wọn yóo rọ;
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nipa ariwo titẹlẹ Patakò ẹsẹ alagbara ẹṣin rẹ̀, nipa iró nla kẹ̀kẹ rẹ̀, ati nipa ariwo nla ayika kẹ̀kẹ rẹ̀; awọn baba kì yio bojuwo ẹhin wò awọn ọmọ wọn nitori ọwọ́ rirọ;
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí wọ́n bá gbọ́ ìró títẹlẹ̀ pátakò ẹsẹ̀ ẹṣin alágbára nígbà tí wọ́n bá gbọ́ ariwo kẹ̀kẹ́ ogun ọ̀tá ńlá àti iye kẹ̀kẹ́ wọn. Àwọn baba kò ní lè ran àwọn ọmọ lọ́wọ́; ọwọ́ wọn yóò kákò.