Jeremiah 47:4 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
nítorí ọjọ́ tí ń bọ̀, tí yóo jẹ́ ọjọ́ ìparun gbogbo àwọn ará Filistia, ọjọ́ tí a óo run gbogbo àwọn olùrànlọ́wọ́ tí ó kù fún Tire ati Sidoni. Nítorí pé OLUWA yóo pa àwọn ará Filistia run, àwọn tí wọ́n kù ní etí òkun ní Kafitori.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori ọjọ na ti mbọ lati pa gbogbo awọn ara Filistia run, ati lati ke gbogbo oluranlọwọ ti o kù kuro lọdọ Tire ati Sidoni: nitori Oluwa yio ṣe ikogun awọn ara Filistia, ani iyokù erekuṣu Kaftori.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí tí ọjọ́ náà ti pé láti pa àwọn Fílístínì run, kí a sì mú àwọn tí ó là tí ó lè ran Tírè àti Sídónì lọ́wọ́ kúrò. OLÚWA ti ṣetán láti pa Fílístínì run, àwọn tí ó kù ní agbègbè Káfútò.