Jeremiah 48:1 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli sọ nípa Moabu pé, “Nebo gbé nítorí yóo di ahoro! Ojú yóo ti Kiriataimu nítorí ogun óo kó o; ìtìjú yóo bá ibi ààbò rẹ̀, wọn óo wó o lulẹ̀;
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
SI Moabu. Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli wi pe, Egbe ni fun Nebo! nitoriti a fi ṣe ijẹ: oju tì Kiriataimu, a si kó o: oju tì Misgabu, o si wariri.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nípa Móábù: Báyìí ni OLÚWA àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí: “Ègbé ni fún Nébò nítorí a ó parun. A dójú ti Kíríátaímù, a sì mú un, ojú yóò ti alágbára, a ó sì fọ́nká.