Jeremiah 48:11 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
OLUWA ní, “Láti ìgbà èwe Moabu ni ó ti ń gbé pẹlu ìrọ̀rùn, kò tíì lọ sí ìgbèkùn rí. Nítorí náà ó silẹ̀ bí gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀ ọtí. A kò máa dà á kiri láti inú ìgò kan sí òmíràn. Adùn rẹ̀ ṣì wà lára rẹ̀, òórùn rẹ̀ kò sì tíì yipada.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Moabu ti wà ni irọra lati igba ewe rẹ̀ wá, o si ti silẹ lori gẹdẹgẹdẹ̀ bi ọtiwaini, a kò si ti dà a lati inu ohun-elo, de ohun-elo bẹ̃ni kò ti ilọ si igbekun: nitorina itọwò rẹ̀ wà ninu rẹ̀, õrun rẹ̀ kò si pada.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Móábù ti wà ní ìsinmi láti ìgbà èwe rẹ̀ wá bí i ọtí wáìnì lórí gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀ rẹ̀, tí a kò dà láti ìgò kan sí èkejì kò tí ì lọ sí ilẹ̀ ìgbèkùn rí. Ó dùn lẹ́nu bí ó ti yẹ, òórùn rẹ̀ kò yí padà.