Jeremiah 48:12 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Nítorí náà, àkókò ń bọ̀, tí n óo jẹ́ kí wọn da Moabu nù, bí ẹni da ọtí nù. Àwọn tí wọn ń da ọtí nù ni n óo rán, tí wọn óo wá tẹ̀ ẹ́ bí ìgò ọtí wọn óo dà á nù patapata, wọn óo sì fọ́ ìgò rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina, wò o, ọjọ mbọ̀, li Oluwa wi, ti emi o rán awọn atẹni-sapakan si i, ti o si tẹ̀ ẹ sapakan, nwọn o si sọ gbogbo ohun-elo rẹ̀ di ofo, nwọn o si fọ ìgo wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n ọjọ́ ń bọ̀,” ni OLÚWA wí, “nígbà tí n ó rán àwọn tí ó da ọtí láti inú àwọn ìgò tí wọ́n ó sì dà á síta; Wọn ó sọ àwọn ìgò rẹ̀ di òfo, wọn ó sì fọ́ àwọn ife rẹ̀.