Jeremiah 48:15 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹni tí yóo pa ilẹ̀ Moabu ati àwọn ìlú rẹ̀ run ti dé, àwọn àṣàyàn ọmọkunrin rẹ̀ sì ti lọ sí ibi tí wọn ó ti pa wọ́n. Èmi ọba, tí orúkọ mi ń jẹ́ OLUWA àwọn ọmọ ogun, ni ó sọ bẹ́ẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
A fi Moabu ṣe ijẹ, ẽfin ilu rẹ̀ si goke lọ, awọn àṣayan ọdọmọkunrin rẹ̀ si sure lọ si ibi pipa, li Ọba wi, ẹniti orukọ rẹ̀ ijẹ, Oluwa awọn ọmọ-ogun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
A ó pa Móábù run, a ó sì gba àwọn ìlú rẹ̀; a ó sì dúńbú àwọn arẹwà ọkùnrin rẹ̀,” ni Ọba wí, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ OLÚWA àwọn ọmọ-ogun.