Jeremiah 48:18 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Sọ̀kalẹ̀ kúrò ninu ògo rẹ, kí o jókòó lórí ìyàngbẹ ilẹ̀, ìwọ tí ò ń gbé Diboni! Nítorí pé ẹni tí óo pa Moabu run ti dojú kọ ọ́, ó sì ti wó àwọn ibi ààbò rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Iwọ olugbe ọmọbinrin Diboni, sọkalẹ lati inu ogo, ki o si ma gbe ibi ongbẹ; nitori afiniṣe-ijẹ. Moabu yio goke wá sori rẹ, yio si pa ilu olodi rẹ run.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Sọ̀kalẹ̀ níbi ògo rẹ, kí o sì jókòó ní ilẹ̀ gbígbẹ, ẹ̀yin olùgbé ọmọbìnrin Díbónì, nítorí tí ẹni tí ó pa Móábù run yóò dojúkọ ọ́ yóò sì pa àwọn ìlú olódi rẹ run.