Jeremiah 48:2 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
ògo Moabu ti dópin! Wọ́n ń pète ibi sí i ní Heṣiboni, wọ́n ní, ‘Ẹ jẹ́ kí á lọ pa á run, kí ó má jẹ́ orílẹ̀-èdè mọ́!’ Ẹ̀yin ará Madimeni pàápàá, kẹ́kẹ́ yóo pa mọ yín lẹ́nu; ogun yóo máa le yín kiri.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ogo Moabu kò si mọ: nwọn ti gbero ibi si i ni Heṣboni pe, wá, ki ẹ si jẹ ki a ke e kuro lati jẹ orilẹ-ède. A o ke ọ lulẹ pẹlu iwọ Madmeni; idà yio tẹle ọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Móábù kò ní ní ìyìn mọ́, ní Héṣíbónì ni wọn ó pète ìparun rẹ̀, ‘Wá, kí a pa orílẹ̀ èdè náà run.’ Àti ẹ̀yin òmùgọ̀ ọkùnrin pàápàá ni a ó pa lẹ́nu mọ́, a ó fi idà lé e yín.