Jeremiah 48:27 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Moabu, ṣebí ò ń fi Israẹli ṣe yẹ̀yẹ́? Ṣé o bá a láàrin àwọn ọlọ́ṣà ni, tí ó fi jẹ́ pé nígbàkúùgbà tí o bá ń sọ̀rọ̀ rẹ̀, ń ṣe ni o máa ń mi orí rẹ?
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Kò ha ri bẹ̃ pe: Israeli jẹ ẹni ẹlẹyà fun ọ bi? bi ẹnipe a ri i lãrin awọn ole? nitori ni igbakũgba ti iwọ ba nsọ̀rọ rẹ̀, iwọ a ma mì ori rẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ǹjẹ́ Ísírẹ́lì kò di ẹni ẹ̀gan rẹ? Ǹjẹ́ a kó o pẹ̀lú àwọn olè tó bẹ́ẹ̀ tí o ń gbọn orí rẹ̀ pẹ̀lú yẹ̀yẹ́ nígbákùúgbà bí a bá sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀?