Jeremiah 48:33 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wọ́n ti mú ayọ̀ ati ìdùnnú kúrò ní ilẹ̀ ọlọ́ràá Moabu; mo ti mú kí ọtí waini tán níbi tí wọ́n ti ń ṣe é, kò sí ẹni tí ó ń ṣe ọtí waini pẹlu ariwo ayọ̀ mọ́, ariwo tí wọn ń pa kì í ṣe ti ayọ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati ayọ̀ ati ariwo inu-didùn li a mu kuro li oko, ati kuro ni ilẹ Moabu; emi si ti mu ki ọti-waini tán ninu ifunti: ẹnikan kì o fi ariwo tẹ̀ ọti-waini; ariwo ikore kì yio jẹ ariwo ikore mọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ayọ̀ àti ìdùnnú ti kúrò nínú ọgbà àjàrà àti oko Móábù, mo dá ọwọ́ ṣíṣàn ọtí wáìnì dúró lọ́dọ̀ olùfúnni; kò sí ẹni tí ó ń tẹ̀ wọ́n pẹ̀lú igbe ayọ̀ Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kì í ṣe ti ayọ̀.