Jeremiah 48:38 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Gbogbo eniyan ń sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn ní gbogbo orí ilé Moabu, ati àwọn ìta gbangba rẹ̀. Nítorí pé mo ti fọ́ Moabu, bíi ohun èlò tí ẹnikẹ́ni kò bìkítà fún. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹkún nlanla ni yio wà lori gbogbo orule Moabu, ati ni ita rẹ̀: nitori emi ti fọ́ Moabu bi ati ifọ́ ohun-elo, ti kò wù ni, li Oluwa wi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní gbogbo orílẹ̀ èdè Móábù àti ní ita kò sí ohun kan bí kò ṣe ọ̀fọ̀, nítorí tí mo fọ́ Móábù bí a ti ń fọ́ ohun elò tí kò wu ni,” ni OLÚWA wí.