Jeremiah 48:39 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
A ti fọ́ Moabu túútúú! Ẹ̀ ń sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn! Moabu pẹ̀yìndà pẹlu ìtìjú! Moabu wá di ẹni yẹ̀yẹ́ ati ẹni àríbẹ̀rù fún gbogbo àwọn tí wọ́n yí i ká.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹ hu, pe, bawo li a ti wo o lulẹ! bawo ni Moabu ti fi itiju yi ẹhin pada! bẹ̃ni Moabu yio di ẹ̀gan ati idãmu si gbogbo awọn ti o yi i kakiri.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Èéṣe tí ẹ fi fọ́ túútúú, tí ẹ sì fi ń pohùnréré ẹkún! Báwo ni Móábù ṣe yí ẹ̀yìn padà ní ìtìjú! Móábù ti di ẹni ìtìjú àti ẹ̀gàn àti ìdààmú sí gbogbo àwọn tí ó yìí ká.”