Jeremiah 48:44 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹni tí ó ń sálọ nítorí ìpayà, yóo jìn sinu ọ̀gbun, ẹni tí ó bá sì jáde ninu ọ̀gbun yóo kó sinu tàkúté. N óo mú kí àwọn nǹkan wọnyi dé bá Moabu nígbà tí àkókò ìjìyà rẹ̀ bá tó. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹniti o ba sa fun ẹ̀ru yio ṣubu sinu ọ̀fin; ati ẹniti o ba jade kuro ninu ọ̀fin ni a o mu ninu okùn-didẹ: nitori emi o mu wá sori rẹ̀, ani sori Moabu, ọdun ibẹ̀wo wọn, li Oluwa wi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ẹnikẹ́ni tí ó bá sá fún ẹ̀rù yóò ṣubú sínú ọ̀fìn ẹnikẹ́ni tí o bá jáde síta nínú ọ̀fìn ní à ó mú nínú okùn dídè nítorí tí èmi yóò mú wá sórí Móábù àní ọdún Ìjìyà rẹ,” ní OLÚWA wí.