Jeremiah 48:45 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn tí wọn ń sá fún ogun dúró ní ibi ààbò Heṣiboni, wọn kò lágbára mọ́, nítorí iná ṣẹ́ jáde láti Heṣiboni ahọ́n iná sì yọ láàrin ilé Sihoni ọba; iná ti jó Moabu tíí ṣe adé àwọn ọmọ onídàrúdàpọ̀ ní àjórun,
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn ti o sá, duro li aini agbara labẹ ojiji Heṣboni: ṣugbọn iná yio jade wá lati Heṣboni, ati ọwọ-iná lati ãrin Sihoni, yio si jẹ ilẹ Moabu run, ati agbari awọn ọmọ ahoro.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ní abẹ́ òjìji Hésíbónì àwọn tí ó sá dúró láìní olùrànlọ́wọ́ nítorí iná ti jáde wá láti Hésíbónì àti ọwọ́ iná láti àárin Síónì sì jó iwájú orí Móábù run àti agbárí àwọn ọmọ àlùfáà.