Jeremiah 48:7 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Ọwọ́ yóo tẹ ìwọ náà, Moabu, nítorí pé o gbójú lé ibi ààbò ati ọrọ̀ rẹ. Oriṣa Kemoṣi yóo lọ sí ìgbèkùn, pẹlu àwọn babalóòṣà ati àwọn ìjòyè rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Njẹ nitoriti iwọ ti gbẹkẹle iṣẹ ọwọ rẹ ati le iṣura rẹ, a o si kó iwọ pẹlu: Kemoṣi yio si jumọ lọ si ìgbekun, pẹlu awọn alufa rẹ̀, ati awọn ijoye rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Níwọ̀n ìgbà tí o gbẹ́kẹ̀lé agbára àti ọrọ̀ rẹ, a ó kó ìwọ náà ní ìgbèkùn, Sémọ́sì náà yóò lọ sí ilẹ̀ ìgbèkùn pẹ̀lú àlùfáà àti àwọn aláṣẹ rẹ̀.