Jeremiah 48:9 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹ bá Moabu wá ìyẹ́, nítorí yóo fò bí ẹyẹ; àwọn ìlú rẹ̀ yóo di ahoro, kò ní ku ẹnikẹ́ni ninu wọn.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Fi iyẹ fun Moabu, ki o ba le fò ki o si lọ, ilu rẹ̀ yio si di ahoro, laisi ẹnikan lati gbe inu rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Fi iyọ̀ sí Móábù, nítorí yóò ṣègbé, àwọn ìlú rẹ yóò sì di ahoro láìsí ẹni tí yóò gbé inú rẹ̀.