Jeremiah 49:1 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ohun tí OLUWA sọ nípa àwọn ará Amoni nìyí: Ó ní, “Ṣé Israẹli kò lọ́mọ ni? Tabi kò ní àrólé? Kí ló dé tí àwọn tí ń bọ Milikomu ṣe gba ilẹ̀ ẹ̀yà Gadi, tí wọ́n sì fi àwọn ìlú Gadi ṣe ibùjókòó?
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
SI awọn ọmọ Ammoni. Bayi li Oluwa wi; Israeli kò ha ni awọn ọmọkunrin? kò ha ni arole bi? nitori kini Malkomu ṣe jogun Gadi, ti awọn enia rẹ̀ si joko ni ilu rẹ̀?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nípa ti Ámónì: Ohun tí OLÚWA sọ nìyìí: “Ísírẹ́lì kò ha ní ọmọkùnrin? Ṣé kò ha ní àrólé bí? Kí ló wá dé tí Mákómù fi jogún Gádì? Kí ló dé tí àwọn ènìyàn rẹ̀ ń gbé ìlú rẹ̀?